Exodus 1:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn pẹlu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ líle. Wọ́n ń po yẹ̀ẹ̀pẹ̀, wọ́n ń mọ bíríkì, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu oko. Pẹlu ìnira ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi ìsin lile, li erupẹ ati ni briki ṣiṣe, ati ni oniruru ìsin li oko mu aiye wọn korò: gbogbo ìsin wọn ti nwọn mu wọn sìn, asìnpa ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ ẹ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Éjíbítì ń lò wọ́n ní ìlòkulò.