Exodus 1:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Farao bá pàṣẹ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkunrin tí àwọn Heberu bá bí, ẹ máa gbé wọn sọ sinu odò Naili, ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọmọbinrin wọn sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Farao si paṣẹ fun gbogbo awọn enia rẹ̀, wipe, Gbogbo ọmọkunrin ti a bí on ni ki ẹnyin gbé jù sinu odò, gbogbo awọn ọmọbinrin ni ki ẹnyin ki o dasi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé; “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Náílì, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láàyè.”