Exodus 10:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá pe Mose, ó ní, “Wọlé tọ Farao lọ, nítorí pé mo tún ti mú ọkàn rẹ̀ le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ: nitoriti mo mu àiya rẹ̀ le, ati àiya awọn iranṣẹ rẹ̀, ki emi ki o le fi iṣẹ-àmi mi wọnyi hàn niwaju rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Fáráò, mo ti ṣé ọkàn Fáráò le àti ọkàn àwọn ìjòyè rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.