Exodus 10:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn eṣú na si goke sori ilẹ Egipti gbogbo, nwọn si bà si ẹkùn Egipti gbogbo; nwọn papọ̀ju, kò si irú eṣú bẹ̃ ṣaju wọn, bẹ̃ni lẹhin wọn irú wọn ki yio si si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu Esú bẹ́ẹ̀, rí kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí.