Exodus 10:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀ oòrùn wá láti gbá àwọn Esú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Éjíbítì lọ sínú òkun pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ Esú kan kò ṣẹ́ kù sí orí ilẹ̀ Éjíbítì.