Exodus 10:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ẹ̀yin náà sì lè sọ fún àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ yín, irú ohun tí mo fi ojú wọn rí, ati irú iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe láàrin wọn; kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ki iwọ ki o le wi li eti ọmọ rẹ, ati ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun ti mo ṣe ni Egipti, ati iṣẹ-àmi mi ti mo ṣe ninu wọn; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yin àti àwọn ọmọ ọmọ yín; Bí mo ti jẹ àwọn ará Éjíbítì níyà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”