Exodus 10:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí okùnkùn báà le bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì; àní òkùnkùn biribiri.”