Exodus 10:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè ó sì wí fún un pé, “Lọ sìn OLÚWA, kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀.”