Exodus 10:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si wi fun u pe, Bayi li OLUWA Ọlọrun Heberu wi, Iwọ o ti kọ̀ pẹ tó lati rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi? jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, ti wọn sí wí fún pé, “Èyí ni OLÚWA, Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ: ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi?