Exodus 10:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si bò oju ilẹ ti ẹnikan ki yio fi le ri ilẹ: nwọn o si jẹ ajẹkù eyiti o bọ́, ti o kù fun nyin lọwọ yinyin, yio si jẹ igi nyin gbogbo ti o nruwe ninu oko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ.