Exodus 10:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose dáhùn pé, “Gbogbo wa ni à ń lọ, ati àgbà ati èwe; ati ọkunrin ati obinrin, ati gbogbo agbo mààlúù wa, ati gbogbo agbo ẹran wa, nítorí pé a níláti lọ ṣe àjọ̀dún kan fún OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wipe, Awa o lọ ati ewe ati àgba, ati awọn ọmọkunrin wa ati awọn ọmọbinrin wa, pẹlu awọn agbo, ati ọwọ́-ẹran wa li awa o lọ; nitori ajọ OLUWA ni fun wa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe ajọ fún OLÚWA.”