Exodus 11:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o tun mú iyọnu kan wá sara Farao, ati sara Egipti; lẹhin eyinì ni on o jọwọ nyin lọwọ lọ lati ihin: nigbati on o jẹ ki ẹ lọ, àtitán ni yio tì nyin jade nihin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísínsìn yìí, OLÚWA sọ fún Mósè pé èmi yóò mú ìyọnu kan sí i wá sí orí Fáráò àti ilẹ̀ Éjíbítì. Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yín kí ó lọ kúrò níhín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá.