Exodus 11:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose ati Aaroni ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí wọn ṣe níwájú Farao, ṣugbọn OLUWA sì mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose ati Aaroni si ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu wọnyi niwaju Farao: OLUWA si mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si fẹ́ jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o jade lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè àti Árónì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Fáráò, ṣùgbọ́n OLÚWA sé ọkàn Fáráò le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni orílẹ̀ èdè rẹ̀.