Exodus 11:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(OLÚWA jẹ́ kí wọn rí ojú rere àwọn ará Éjíbítì, pàápàá, Mósè fún ra rẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Éjíbítì ní iwájú àwọn ìjòyè Fáráò àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú).