Exodus 11:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ajá kò tilẹ̀ ní gbó ẹnikẹ́ni tabi ẹran ọ̀sìn kan, jákèjádò ààrin àwọn ọmọ Israẹli; kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA fi ìyàtọ̀ sí ààrin àwọn ará Ijipti ati àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn.’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé OLÚWA ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Éjíbítì àti Ísírẹ́lì.