Exodus 11:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ wọnyi yóo sì tọ̀ mí wá, wọn yóo fi orí balẹ̀ fún mi, wọn yóo wí pé kí n máa lọ, èmi ati gbogbo àwọn eniyan mi! Lẹ́yìn náà ni n óo jáde lọ.” Mose bá fi tìbínú-tìbínú jáde kúrò níwájú Farao.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀ lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mósè fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Fáráò