Exodus 12:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijọ́ meje li ẹ o fi ma jẹ àkara alaiwu; li ọjọ́ kini gan li ẹ o palẹ iwukàra mọ́ kuro ni ile nyin; nitori ẹniti o ba jẹ àkara wiwu lati ọjọ́ kini lọ titi o fi di ọjọ́ keje, ọkàn na li a o ke kuro ninu Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Ísírẹ́lì.