Exodus 12:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kinni ati ní ọjọ́ keje, ẹ óo péjọ pọ̀ láti jọ́sìn. Ní ọjọ́ mejeeje yìí, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, àfi oúnjẹ tí ẹ óo bá jẹ nìkan ni ẹ lè sè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà, ati li ọjọ́ keje apejọ mimọ́ yio wà fun nyin; a ki yio ṣe iṣẹkiṣẹ ninu wọn, bikoṣe eyiti olukuluku yio jẹ, kìki eyinì li a le ṣe ninu nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ pe àpèjọ mímọ́, kí ẹ sì pe àpèjọ mímọ́ mìíràn ni ọjọ́ keje. Ẹ má ṣe se iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, yàtọ̀ fún pípèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn láti jẹ: Èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe.