Exodus 12:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu ilé yín fún ọjọ́ mejeeje, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́, kì báà jẹ́ àlejò tabi onílé ní ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọ́dọ́ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárin àwùjọ Ísírẹ́lì, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà.