Exodus 12:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà tí OLÚWA bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Éjíbítì láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé yín, yóò sì re ẹnu ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láàyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín.