Exodus 12:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí OLÚWA ni, ẹni tí ó rékọjá ilé e wa ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Éjíbítì. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Éjíbítì.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn.