Exodus 12:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù yìí, ọkunrin kọ̀ọ̀kan ninu ìdílé kọ̀ọ̀kan yóo mú ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan tabi àwọ́nsìn kọ̀ọ̀kan; ọ̀dọ́ aguntan kan fún ilé kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ sọ fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli pe, Ni ijọ́ kẹwa oṣù yi ni ki olukuluku wọn ki o mú ọdọ-agutan sọdọ, gẹgẹ bi ile baba wọn, ọdọ-agutan kan fun ile kan:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì pé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan yóò mú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan fún ìdílé rẹ̀, ọ̀kan fún agbo ilé kọ̀ọ̀kan.