Exodus 12:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Egipti si nrọ̀ awọn enia na, ki nwọn ki o le rán wọn jade lọ kuro ni ilẹ na kánkan; nitoriti nwọn wipe, Gbogbo wa di okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ara Éjíbítì ń rọ àwọn ènìyàn náà láti yára máa lọ kúrò ní ilẹ̀ wọn. Wọ́n wí pé, “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ gbogbo wa ni yóò kú!”