Exodus 12:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ìyẹ̀fun tí kò ní ìwúkàrà nínú tí wọ́n gbé jáde láti Éjíbítì wá ní wọ́n fi ṣe àkàrà aláìwú. Ìyẹ̀fun náà kò ni ìwúkàrà nínú nítorí a lé wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wọn kò si rí ààyè láti tọ́jú oúnjẹ fún ara wọn.