Exodus 12:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ìdílé kan bá wà tí ó kéré jù láti jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan kan tán, ìdílé yìí yóo darapọ̀ mọ́ ìdílé mìíràn ní àdúgbò rẹ̀, wọn yóo sì pín ẹran tí wọ́n bá pa gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí ó wà ninu ìdílé mejeeji, iye eniyan tí ó bá lè jẹ àgbò kan tán ni yóo darapọ̀ láti pín ọ̀dọ́ aguntan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ara ile na ba si kere jù ìwọn ọdọ-agutan na lọ, ki on ati aladugbo rẹ̀ ti o sunmọ-eti ile rẹ̀, ki o mú gẹgẹ bi iye awọn ọkàn na, olukuluku ni ìwọn ijẹ rẹ̀ ni ki ẹ ṣiro ọdọ-agutan na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìdílé kan bá kéré jù fún odidi ọ̀dọ́ àgùntàn kan, kí wọn kí ó ṣe àjọpín ọ̀kan pẹ̀lú aládùúgbò wọn ti ó sun mọ́ wọn kí wọ́n lo iye ènìyàn ti wọn jẹ láti ṣe òdìnwọ̀n irú ọ̀dọ́ àgùntàn ti wọn yóò lò ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀n ti ẹni kọ̀ọ̀kan lè jẹ.