Exodus 12:48 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àlejò kan bá wọ̀ sí ilé yín, tí ó bá sì fẹ́ bá yín ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá, ó gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé rẹ̀ ní ilà abẹ́, lẹ́yìn náà, ó lè ba yín ṣe àjọ̀dún náà, òun náà yóo dàbí olùgbé ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ ilà abẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àjọ ìrékọjá náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati alejò kan ba nṣe atipo lọdọ rẹ, ti o si nṣe ajọ irekọja si OLUWA, ki a kọ gbogbo ọkunrin rẹ̀ nilà, nigbana ni ki ẹ jẹ ki o sunmọtosi, ki o si ṣe e; on o si dabi ẹniti a bi ni ilẹ na: nitoriti kò si ẹni alaikọlà ti yio jẹ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àjòjì ti ó bá ń gbé ní àárin yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá OLÚWA, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ìlà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ìlà, wọ́n kò ni jẹ ni ara rẹ̀.