Exodus 12:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si fi i pamọ́ titi o fi di ijọ́ kẹrinla oṣù na: gbogbo agbajọ ijọ Israeli ni yio pa a li aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mójúmọ́.