Exodus 12:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóo fi kun àtẹ́rígbà ati ara òpó ìlẹ̀kùn mejeeji ilé tí wọn yóo ti jẹ ẹran náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si mú ninu ẹ̀jẹ na, nwọn o si fi tọ́ ara opó ìha mejeji, ati sara atẹrigba ile wọnni, ninu eyiti nwọn o jẹ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò fi kan ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti òkè ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níbi tí wọ́n bá ti jẹ ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn náà.