Exodus 13:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ iwájú bí àwọn ọmọkunrin yín bá bèèrè ìtumọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́ yín, ohun tí ẹ óo wí fún wọn ni pé, ‘Pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a ti wà ní ìgbèkùn rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe nigbati ọmọ rẹ yio bère lọwọ rẹ lẹhin-ọla pe, Kili eyi? ki iwọ ki o wi fun u pe, Ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni ilẹ Egipti, kuro li oko-ẹrú:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní OLÚWA fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, kúrò ní oko ẹrú.