Exodus 13:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sì ń lọ níwájú wọn ní ọ̀sán ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu láti máa fi ọ̀nà hàn wọ́n, ati ní òru, ninu ọ̀wọ̀n iná láti máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀sán ati ní òru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si nlọ niwaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma li ọsán, lati ma ṣe amọna fun wọn; ati li oru li ọwọ̀n iná lati ma fi imọlẹ fun wọn; lati ma rìn li ọsán ati li oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì ń lọ níwájú wọn, nínú òpó ìkùùkuu ní ọ̀san láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú òpó iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru.