Exodus 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọjọ́ meje li a o fi jẹ àkara alaiwu; ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ, bẹ̃ni ki a má si ṣe ri iwukàra lọdọ rẹ ni gbogbo ẹkùn rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.