Exodus 13:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣiṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ìránlétí ni iwájú orí rẹ tí yóò máa ran ọ létí òfin OLÚWA ní ẹnu rẹ. Nítorí OLÚWA mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.