Exodus 14:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọrọ yi ki awa ti sọ fun ọ ni Egipti pe, Jọwọ wa jẹ ki awa ki o ma sìn awọn ara Egipti? O sá san fun wa lati ma sin awọn ara Egipti, jù ki awa kú li aginjù lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Éjíbítì, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Éjíbítì’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Éjíbítì ju kí a kú sínú ihà yìí lọ!”