Exodus 14:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo mú kí ọkàn àwọn ará Ijipti le, kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, n óo sì gba ògo lórí Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni èmi yóò ṣé ọkàn àwọn ará Éjíbítì le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Fáráò; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́-ògun àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.