Exodus 14:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Ijipti ati àwọn ọmọ ogun Israẹli, ìkùukùu náà ṣókùnkùn dudu títí tí gbogbo òru ọjọ́ náà fi kọjá, wọn kò sì súnmọ́ ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Éjíbítì àti Ísírẹ́lì. Ìkùùkuu sì su òkùnkùn sí àwọn ará Éjíbítì ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Ísírẹ́lì ni òru náà; Ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.