Exodus 14:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Omi òkun pada sí ipò rẹ̀, ó sì bo gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ati àwọn ọmọ ogun Farao tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, ẹyọ kan kò sì yè ninu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Omi si pada, o si bò kẹkẹ́, ati awọn ẹlẹṣin, ati gbogbo ogun Farao ti o wọ̀ inu okun tọ̀ wọn lẹhin lọ; ọkanṣoṣo kò kù ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin: àní, gbogbo ọmọ ogun Fáráò ti wọn wọ inú òkun tọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn ti o yè.