Exodus 14:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo tún mú kí ọkàn Farao le, yóo lépa yín, n óo sì gba ògo lórí Farao ati ogun rẹ̀, àwọn ará Ijipti yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bí OLUWA ti wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sé ọkàn Fáráò le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpaṣẹ̀ Fáráò àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.” Àwọn Isírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀.