Exodus 14:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n sọ fún Farao, ọba Ijipti, pé àwọn ọmọ Israẹli ti sálọ, èrò òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nípa àwọn eniyan náà yipada. Wọ́n wí láàrin ara wọn pé, “Irú kí ni a ṣe yìí, tí a jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi lọ mọ́ wa lọ́wọ́, tí a kò jẹ́ kí wọ́n ṣì máa sìn wá?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si wi fun ọba Egipti pe, awọn enia na sá: àiya Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀ si yi si awọn enia na, nwọn si wipe, Ẽṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu ìsin wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Éjíbítì pé àwọn ènìyàn náà ti sá lọ, ọkàn Fáráò àti àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.”