Exodus 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Ijipti ń lé wọn lọ, pẹlu gbogbo ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun Farao, ati gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ati gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n pàgọ́ sí lẹ́bàá òkun, lẹ́bàá Pi Hahirotu ni òdìkejì Baali Sefoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ara Egipti lepa wọn, gbogbo ẹṣin ati kẹkẹ́ Farao, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, ati awọn ogun rẹ̀, o si lé wọn bá, nwọn duro li ẹba okun ni ìha Pi-hahirotu niwaju Baal-sefoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Éjíbítì ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹsin kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bá òkun ní ìhà Pi-Hahírótù, ni òdì kejì Baali-Ṣéfónì.