Exodus 15:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA, nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo. Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí OLÚWA: Èmi yóò kọrin sí OLÚWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹsin àti ẹni tí ó gùn un ni ó ti sọ sínú òkun.