Exodus 15:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati jìnnìjìnnì ti dà bò wọ́n, nítorí títóbi agbára rẹ, OLUWA, wọ́n dúró bí òkúta, títí tí àwọn eniyan rẹ fi kọjá lọ, àní àwọn tí o ti rà pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibẹru-bojo mú wọn; nipa titobi apa rẹ nwọn duro jẹ bi okuta; titi awọn enia rẹ fi rekọja, OLUWA, titi awọn enia rẹ ti iwọ ti rà fi rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbẹ̀rù-bojo yóò subú lù wọ́n nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ ẹ́ láì mira bí i òkúta Títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi ré kọjá, OLÚWA, Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi ré kọjá.