Exodus 15:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O óo kó àwọn eniyan rẹ wọlé, o óo sì fi ìdí wọn múlẹ̀ lórí òkè mímọ́ rẹ, níbi tí ìwọ OLUWA ti pèsè fún ibùgbé rẹ, ibi mímọ́ rẹ tí ìwọ OLUWA ti fi ọwọ́ ara rẹ pèsè sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o mú wọn wọle, iwọ o si gbìn wọn sinu oke ilẹ-iní rẹ, OLUWA, ni ibi ti iwọ ti ṣe fun ara rẹ, lati mã gbé, OLUWA; ni ibi mimọ́ na, ti ọwọ́ rẹ ti gbekalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni ori òkè ti ìwọ jogún; Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, OLÚWA. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, OLÚWA.