Exodus 15:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú láti ibi Òkun Pupa, wọ́n ń lọ sí aṣálẹ̀ Ṣuri, ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi rìn ninu aṣálẹ̀ láìrí omi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Mose mú Israeli jade lati Okun Pupa wá, nwọn si jade lọ si ijù Ṣuri; nwọn si lọ ni ìrin ijọ́ mẹta ni ijù na, nwọn kò si ri omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti òkun pupa lọ sínú aṣálẹ̀ Ṣúrì. Wọ́n lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi.