Exodus 16:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli jáde kúrò ní Elimu, wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini tí ó wà ní ààrin Elimu ati Sinai, ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keji tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Élímù, wọ́n dé sí ijù Sínì tí ó wà láàrin Élímù àti Ṣínáì, ni ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.