Exodus 16:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe bí Árónì ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọn si bojúwo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo OLÚWA si farahàn ni àwọ̀-sánmọ̀.