Exodus 16:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ti Mose; bẹ̃li ẹlomiran si kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, o si di idin, o si rùn; Mose si binu si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mósè bínú sí wọn.