Exodus 16:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá sọ fún Aaroni pé, “Mú ìkòkò kan kí o fi ìwọ̀n omeri mana kan sinu rẹ̀, kí o gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA, kí ẹ pa á mọ́ láti ìrandíran yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Aaroni pe, Mú ìkoko kan, ki o si fi òṣuwọn omeri kan ti o kún fun manna sinu rẹ̀, ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA, lati pa a mọ́ fun irandiran nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó mánà tí ó kún òṣùnwọ̀n ómérì kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú OLÚWA láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”