Exodus 16:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose sọ fún Aaroni pé, “Sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, kí wọ́n súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ OLUWA, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si sọ fun Aaroni pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ iwaju OLUWA, nitoriti o ti gbọ́ kikùn nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pe, ‘Ẹ wá sí iwájú OLÚWA, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”