Exodus 17:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli gbéra láti aṣálẹ̀ Sini, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ibùsọ̀ kan dé ekeji, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣugbọn kò sí omi fún wọn láti mu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si rìn lati ijù Sini lọ, ni ìrin wọn, gẹgẹ bi ofin OLUWA, nwọn si dó ni Refidimu: omi kò si si fun awọn enia na lati mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì si gbéra láti jáde kúrò láti ihà Sínì wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Réfídímù Ṣugbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú.