Exodus 17:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Kọ eyi sinu iwe fun iranti, ki o si kà a li eti Joṣua; nitoriti emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fun Mósè pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Jóṣúà pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìràntí Ámélékì run pátapáta kúrò lábẹ́ ọ̀run.”